5. Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.
6. Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀.
7. Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi.
8. Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.