9. Emi o si ṣe ile Ahabu bi ile Jeroboamu ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa ọmọ Ahijah;
10. Awọn aja yio si jẹ Jesebeli ni oko Jesreeli, kì yio si ẹniti yio sinkú rẹ̀. O si ṣi ilẹkùn, o si sá lọ.
11. Nigbana ni Jehu jade tọ̀ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀: ẹnikan si wi fun u pe, Alafia kọ́? nitori kini aṣiwère yi ṣe tọ̀ ọ wá? On si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ọkunrin na ati ọ̀rọ rẹ̀.
12. Nwọn si wipe, Eke; sọ fun wa wayi. On si wipe, Bayi bayi li o sọ fun mi wipe, Bayi ni Oluwa wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori Israeli.
13. Nigbana ni nwọn yára, olukulùku si mu agbáda rẹ̀, o si fi i si abẹ rẹ̀ lori atẹ̀gun, nwọn si fun ipè wipe, Jehu jọba.
14. Bẹ̃ni Jehu ọmọ Jehoṣafati ọmọ Nimṣi ṣotẹ si Joramu. (Njẹ Joramu ti nṣọ Ramoti-Gileadi, on, ati gbogbo Israeli, nitoriti Hasaeli ọba Siria:
15. Ṣugbọn Joramu ọba ti pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ṣa a, nigbati o ba Hasaeli ọba Siria jà.) Jehu si wipe, Bi o ba ṣe ifẹ inu nyin ni, ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ki o jade lọ, tabi ki o yọ́ lọ kuro ni ilu lati lọ isọ ni Jesreeli.
16. Bẹ̃ni Jehu gùn kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli; nitori Joramu dùbulẹ nibẹ. Ahasiah ọba Juda si sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu.
17. Olùṣọ kan si duro ni ile iṣọ ni Jesreeli, o si ri ẹgbẹ́ Jehu bi o ti mbọ̀ wá, o si wipe, Mo ri ẹgbẹ́ kan. Joramu si wipe, Mu ẹlẹṣin kan, ki o si ranṣẹ lọ ipade wọn, ki o si wipe, Alafia kọ́?
18. Ẹnikan si lọ lori ẹṣin lati pade rẹ̀, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi. Olùṣọ na si sọ pe, Iranṣẹ na de ọdọ wọn, ṣugbọn kò si tun pada wá mọ.
19. O si rán ekeji jade lori ẹṣin on si tọ̀ wọn wá, o si wipe, Bayi li ọba wi pe, Alafia kọ́? Jehu si dahùn wipe, Kini iwọ ni fi alafia ṣe? yipada sẹhin mi.
20. Olùṣọ na si sọ wipe, On tilẹ de ọdọ wọn, kò si tun padà wá mọ: wiwọ́ kẹkẹ́ na si dàbi wiwọ́ kẹkẹ́ Jehu ọmọ Nimṣi; nitori o nwọ́ bọ̀ kikankikan.
21. Joramu si wipe, Ẹ dì kẹkẹ́. Nwọn si dì kẹkẹ́ rẹ̀. Joramu ọba Israeli ati Ahasiah ọba Juda si jade lọ, olukulùku ninu kẹkẹ́ rẹ̀, nwọn si jade lọ ipade Jehu, nwọn si ba a ni oko Naboti ara Jesreeli.