4. Bẹ̃ni ọdọmọkunrin na, ani ọdọmọkunrin woli na, lọ si Ramoti-Gileadi.
5. Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun.
6. On si dide, o si wọ̀ inu ile: o si tú ororo na si i li ori, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia Oluwa, lori Israeli.
7. Iwọ o si kọlù ile Ahabu oluwa rẹ, ki emi o le gbẹsan ẹjẹ awọn woli iranṣẹ mi, ati ẹ̀jẹ gbogbo awọn iranṣẹ Oluwa lọwọ Jesebeli.
8. Nitori gbogbo ile Ahabu ni yio ṣegbé: emi o si ké gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Ahabu ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli:
9. Emi o si ṣe ile Ahabu bi ile Jeroboamu ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa ọmọ Ahijah;
10. Awọn aja yio si jẹ Jesebeli ni oko Jesreeli, kì yio si ẹniti yio sinkú rẹ̀. O si ṣi ilẹkùn, o si sá lọ.
11. Nigbana ni Jehu jade tọ̀ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀: ẹnikan si wi fun u pe, Alafia kọ́? nitori kini aṣiwère yi ṣe tọ̀ ọ wá? On si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ọkunrin na ati ọ̀rọ rẹ̀.
12. Nwọn si wipe, Eke; sọ fun wa wayi. On si wipe, Bayi bayi li o sọ fun mi wipe, Bayi ni Oluwa wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori Israeli.
13. Nigbana ni nwọn yára, olukulùku si mu agbáda rẹ̀, o si fi i si abẹ rẹ̀ lori atẹ̀gun, nwọn si fun ipè wipe, Jehu jọba.
14. Bẹ̃ni Jehu ọmọ Jehoṣafati ọmọ Nimṣi ṣotẹ si Joramu. (Njẹ Joramu ti nṣọ Ramoti-Gileadi, on, ati gbogbo Israeli, nitoriti Hasaeli ọba Siria:
15. Ṣugbọn Joramu ọba ti pada si Jesreeli lati wò ọgbẹ́ ti awọn ara Siria ṣa a, nigbati o ba Hasaeli ọba Siria jà.) Jehu si wipe, Bi o ba ṣe ifẹ inu nyin ni, ẹ má jẹ ki ẹnikẹni ki o jade lọ, tabi ki o yọ́ lọ kuro ni ilu lati lọ isọ ni Jesreeli.
16. Bẹ̃ni Jehu gùn kẹkẹ́, o si lọ si Jesreeli; nitori Joramu dùbulẹ nibẹ. Ahasiah ọba Juda si sọ̀kalẹ lati wá iwò Joramu.