2. A. Ọba 9:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nigbati iwọ ba si de ibẹ, ki iwọ ki o wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi li awari nibẹ, ki o si wọle, ki o si mu u ki o dide kuro lãrin awọn arakunrin rẹ̀, ki o si mu u lọ si yàra inu ile lọhun;

3. Ki o si mu igò ororo na, ki o si tú u si ori rẹ̀, ki o si wipe, Bayi li Oluwa wipe, Emi fi ororo yàn ọ li ọba li ori Israeli. Si ṣi ilẹkun, ki o si sá, má si ṣe duro.

4. Bẹ̃ni ọdọmọkunrin na, ani ọdọmọkunrin woli na, lọ si Ramoti-Gileadi.

5. Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun.

6. On si dide, o si wọ̀ inu ile: o si tú ororo na si i li ori, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia Oluwa, lori Israeli.

7. Iwọ o si kọlù ile Ahabu oluwa rẹ, ki emi o le gbẹsan ẹjẹ awọn woli iranṣẹ mi, ati ẹ̀jẹ gbogbo awọn iranṣẹ Oluwa lọwọ Jesebeli.

8. Nitori gbogbo ile Ahabu ni yio ṣegbé: emi o si ké gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Ahabu ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli:

9. Emi o si ṣe ile Ahabu bi ile Jeroboamu ọmọ Nebati, ati bi ile Baaṣa ọmọ Ahijah;

10. Awọn aja yio si jẹ Jesebeli ni oko Jesreeli, kì yio si ẹniti yio sinkú rẹ̀. O si ṣi ilẹkùn, o si sá lọ.

11. Nigbana ni Jehu jade tọ̀ awọn iranṣẹ oluwa rẹ̀: ẹnikan si wi fun u pe, Alafia kọ́? nitori kini aṣiwère yi ṣe tọ̀ ọ wá? On si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ ọkunrin na ati ọ̀rọ rẹ̀.

12. Nwọn si wipe, Eke; sọ fun wa wayi. On si wipe, Bayi bayi li o sọ fun mi wipe, Bayi ni Oluwa wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori Israeli.

2. A. Ọba 9