2. A. Ọba 8:14-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bẹ̃li o lọ kuro lọdọ Eliṣa, o si de ọdọ oluwa rẹ̀; on si wi fun u pe, Kini Eliṣa sọ fun ọ? On si dahùn wipe, O sọ fun mi pe, Iwọ o sàn nitõtọ.

15. O si ṣe ni ijọ keji ni o mu aṣọ ti o nipọn, o kì i bọ̀ omi, o si tẹ́ ẹ le oju rẹ̀, bẹ̃li o kú. Hasaeli si jọba nipò rẹ̀.

16. Ati li ọdun karun Joramu, ọmọ Ahabu ọba Israeli, Jehoṣafati jẹ ọba Juda: nigbana Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda bẹ̀rẹ si ijọba.

17. Ẹni ọdun mejilelọgbọn li o jẹ nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹjọ ni Jerusalemu.

18. O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, bi ile Ahabu ti ṣe: nitori ọmọbinrin Ahabu li o nṣe aya rẹ̀; on si ṣe ibi niwaju Oluwa.

2. A. Ọba 8