Ifi 8:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Mo si ri awọn angẹli meje ti nwọn duro niwaju Ọlọrun; a si fi ipè meje fun wọn.

3. Angẹli miran si wá, o si duro tì pẹpẹ, o ni awo turari wura kan; a si fi turari pupọ̀ fun u, ki o le fi i kún adura gbogbo awọn enia mimọ́ lori pẹpẹ wura ti mbẹ niwaju itẹ́.

4. Ati ẹ̃fin turari na pẹlu adura awọn enia mimọ́ si gòke lọ siwaju Ọlọrun lati ọwọ́ angẹli na wá.

5. Angeli na si mu awo turari na, o si fọ̀n iná ori pẹpẹ kun u, o si dà a sori ilẹ aiye: a si gbọ ohùn, ãra si san, mànamána si kọ, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀.

6. Awọn angẹli meje na ti nwọn ni ipè meje si mura lati fun wọn.

7. Ekini si fun, yinyín ati iná ti o dàpọ̀ pẹlu ẹ̀jẹ si jade, a si dà wọn sori ilẹ aiye: idamẹta ilẹ aiye si jóna, idamẹta awọn igi si jóna, ati gbogbo koriko tutù si jóna.

8. Angẹli keji si fun, a si wọ́ ohun kan bi òke nla ti njona sọ sinu okun: idamẹta okun si di ẹ̀jẹ;

9. Ati idamẹta awọn ẹda ti mbẹ ninu okun ti o ni ẹmí si kú; ati idamẹta awọn ọkọ̀ si bajẹ.

10. Angẹli kẹta si fun, irawọ̀ nla kan ti njo bi fitila si bọ́ lati ọrun wá, o si bọ sori idamẹta awọn odo ṣiṣàn, ati sori awọn orisun omi;

Ifi 8