Ifi 7:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN eyi ni mo ri angẹli mẹrin duro ni igun mẹrẹrin aiye, nwọn di afẹfẹ mẹrẹrin aiye mu, ki o máṣe fẹ́ sori ilẹ, tabi sori okun, tabi sara igikigi.

2. Mo si ri angẹli miran ti o nti ìha ìla-õrùn goke wá, ti on ti èdidi Ọlọrun alãye lọwọ: o si kigbe li ohùn rara si awọn angẹli mẹrin na ti a fifun lati pa aiye ati okun lara,

3. Wipe, Ẹ máṣe pa aiye, tabi okun, tabi igi lara, titi awa o fi fi èdidi sami si awọn iranṣẹ Ọlọrun wa ni iwaju wọn.

4. Mo si gbọ́ iye awọn ẹniti a fi èdidi sami si: awọn ti a sami si jẹ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji lati inu gbogbo ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli wá.

5. Lati inu ẹ̀ya Juda a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Reubeni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Gadi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.

6. Lati inu ẹ̀ya Aṣeri a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Neftalimu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Manasse a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.

7. Lati inu ẹ̀ya Simeoni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Lefi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Issakari a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.

8. Lati inu ẹ̀ya Sebuloni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Josefu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Benjamini a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.

9. Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn;

10. Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ́, ati ti Ọdọ-Agutan.

11. Gbogbo awọn angẹli si duro yi itẹ́ na ká, ati yi awọn àgba ati awọn ẹda alãye mẹrin na ká, nwọn wolẹ nwọn si dojubolẹ niwaju itẹ́ na nwọn si sìn Ọlọrun,

Ifi 7