Ifi 5:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Emi si wò, mo si gbọ́ ohùn awọn angẹli pupọ̀ yi itẹ́ na ká, ati yi awọn ẹda alãye na ati awọn àgba na ká: iye wọn si jẹ ẹgbãrun ọna ẹgbãrun ati ẹgbẹgbẹ̀run ọna ẹgbẹgbẹ̀run;

12. Nwọn nwi li ohùn rara pe, Yiyẹ li Ọdọ-Agutan na ti a ti pa, lati gbà agbara, ati ọrọ̀, ati ọgbọ́n, ati ipá, ati ọlá, ati ogo, ati ibukún.

13. Gbogbo ẹda ti o si mbẹ li ọrun, ati lori ilẹ aiye, ati nisalẹ ilẹ, ati irú awọn ti mbẹ ninu okun, ati gbogbo awọn ti mbẹ ninu wọn, ni mo gbọ́ ti nwipe, Ki a fi ibukún ati ọlá, ati ogo, ati agbara, fun ẹniti o joko lori itẹ́ ati fun Ọdọ-Agutan na lai ati lailai.

14. Awọn ẹda alãye mẹrin na wipe; Amin. Awọn àgba mẹrinlelogun na wolẹ, nwọn si foribalẹ fun ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai.

Ifi 5