Ifi 5:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si ri li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na, iwe kan ti a kọ ninu ati lẹhin, ti a si fi èdidi meje dì.

2. Mo si ri angẹli alagbara kan, o nfi ohùn rara kede pe, Tali o yẹ lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀?

3. Kò si si ẹnikan li ọrun, tabi lori ilẹ aiye, tabi nisalẹ ilẹ, ti o le ṣí iwe na, tabi ti o le wò inu rẹ̀.

4. Emi si sọkun gidigidi, nitoriti a kò ri ẹnikan ti o yẹ lati ṣí ati lati kà iwe na, tabi lati wò inu rẹ̀.

Ifi 5