Ifi 22:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán: ibukún ni fun ẹniti npa ọ̀rọ isọtẹlẹ inu iwe yi mọ́.

8. Emi Johanu li ẹniti o gbọ́ ti o si ri nkan wọnyi. Nigbati mo si gbọ́ ti mo si ri, mo wolẹ lati foribalẹ niwaju ẹsẹ angẹli na, ti o fi nkan wọnyi hàn mi.

9. Nigbana li o wi fun mi pe, Wo o, máṣe bẹ̃: iranṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ li emi, ati ti awọn arakunrin rẹ woli, ati ti awọn ti npa ọ̀rọ inu iwe yi mọ́: foribalẹ fun Ọlọrun.

10. O si wi fun mi pe, Máṣe fi èdidi dí ọ̀rọ isọtẹlẹ ti inu iwe yi: nitori ìgba kù si dẹ̀dẹ̀.

11. Ẹniti iṣe alaiṣõtọ, ki o mã ṣe alaiṣõtọ nṣó: ati ẹniti iṣe ẹlẹgbin, ki o mã ṣe ẹlẹgbin nṣó: ati ẹniti iṣe olododo, ki o mã ṣe olododo nṣó: ati ẹniti iṣe mimọ́, ki o mã ṣe mimọ́ nṣó.

12. Kiyesi i, emi mbọ̀ kánkán; ère mi si mbẹ pẹlu mi, lati san an fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀ yio ti ri.

13. Emi ni Alfa ati Omega, ẹni iṣaju ati ẹni ikẹhin, ipilẹṣẹ̀ ati opin.

14. Ibukún ni fun awọn ti nfọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o le ni anfani lati wá si ibi igi ìye na, ati ki nwọn ki o le gba awọn ẹnubode wọ inu ilu na.

Ifi 22