Ifi 18:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN nkan wọnyi mo si ri angẹli miran, o nti ọrun sọkalẹ wá ti on ti agbara nla; ilẹ aiye si ti ipa ogo rẹ̀ mọlẹ.

2. O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira.

3. Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀.

4. Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀.

5. Nitori awọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gá ani de ọrun, Ọlọrun si ti ranti aiṣedẽdẽ rẹ̀.

6. San a fun u, ani bi on ti san fun-ni, ki o si ṣe e ni ilọpo meji fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: ninu ago na ti o ti kùn, on ni ki ẹ si kún fun u ni meji.

7. Niwọn bi o ti yin ara rẹ̀ logo to, ti o si huwa wọbia, niwọn bẹ̃ ni ki ẹ da a loro ki ẹ si fún u ni ibanujẹ: nitoriti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, mo joko bi ọbabirin, emi kì si iṣe opó, emi ki yio si ri ibinujẹ lai.

8. Nitorina ni ijọ kan ni iyọnu rẹ̀ yio de, ikú, ati ibinujẹ, ati ìyan; a o si fi iná sun u patapata: nitoripe alagbara ni Oluwa Ọlọrun ti nṣe idajọ rẹ̀.

9. Ati awọn ọba aiye, ti o ti mba a ṣe àgbere, ti nwọn si mba a hu iwà wọbia, yio si pohùnrere ẹkún le e lori, nigbati nwọn ba wo ẹ̃fin ijona rẹ̀.

10. Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de.

Ifi 18