2. Ẹniti awọn ọba aiye ba ṣe àgbere, ti a si ti fi ọti-waini àgbere rẹ̀ pa awọn ti ngbe inu aiye.
3. O si gbe mi ninu Ẹmí lọ si aginjù: mo si ri obinrin kan o joko lori ẹranko alawọ̀ odòdó kan ti o kún fun orukọ ọrọ-odi, o ni ori meje ati iwo mẹwa.
4. A si fi aṣọ elese aluko ati aṣọ odòdó wọ obinrin na, a si fi wura ati okuta iyebiye ati perli ṣe e lọṣọ́, o ni ago wura kan li ọwọ́ rẹ̀, ti o kún fun irira ati fun ẹgbin àgbere rẹ̀:
5. Ati niwaju rẹ̀ ni orukọ kan ti a kọ, OHUN IJINLẸ, BABILONI NLA, IYA AWỌN PANṢAGA ATI AWỌN OHUN IRIRA AIYE.
6. Mo si ri obinrin na mu ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́, ati ẹ̀jẹ awọn ajẹrikú Jesu li amuyo: nigbati mo si ri i, ẹnu yà mi gidigidi.
7. Angẹli si wi fun mi pe, Nitori kili ẹnu ṣe yà ọ? emi o sọ ti ijinlẹ obinrin na fun ọ, ati ti ẹranko ti o gùn, ti o ni ori meje ati iwo mẹwa.
8. Ẹranko ti iwọ ri nì, o ti wà, kò si sí mọ́: yio si ti inu ọgbun gòke wá, yio si lọ sinu egbé: ẹnu yio si yà awọn ti ngbé ori ilẹ aiye, orukọ awọn ẹniti a kò ti kọ sinu iwe ìye lati ipilẹṣẹ aiye, nigbati nwọn nwò ẹranko ti o ti wà, ti kò si sí mọ́, ti o si mbọ̀wá.
9. Nihin ní itumọ ti o li ọgbọ́n wà. Ori meje nì oke nla meje ni, lori eyi ti obinrin na joko.
10. Ọba meje si ni nwọn: awọn marun ṣubu, ọkan mbẹ, ọkan iyokù kò si ti ide; nigbati o ba si de, yio duro fun igba kukuru.
11. Ẹranko ti o si ti wà, ti kò si si, on na si ni ẹkẹjọ, o si ti inu awọn meje na wá, o si lọ si iparun.
12. Iwo mẹwa ti iwọ si ri nì ọba mẹwa ni nwọn, ti nwọn kò iti gba ijọba; ṣugbọn nwọn gba ọla bi ọba pẹlu ẹranko na fun wakati kan.