2. Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀.
3. Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.
4. Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ.
5. Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi.
6. Nitoriti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn enia mimọ́ ati ti awọn woli silẹ, iwọ si fi ẹ̀jẹ fun wọn mu; eyiyi li o yẹ wọn.
7. Mo si gbọ́ pẹpẹ nke wipe, Bẹ̃ni, Oluwa Ọlọrun Olodumare, otitọ ati ododo ni idajọ rẹ.
8. Ẹkẹrin si tú ìgo tirẹ̀ sori õrùn; a si yọnda fun u lati fi iná jó enia lara.
9. A si fi õru nla jo awọn enia lara, nwọn si sọ̀rọ-òdi si orukọ Ọlọrun, ẹniti o li agbara lori iyọnu wọnyi: nwọn kò si ronupiwada lati fi ogo fun u.
10. Ẹkarun si tu ìgo tirẹ̀ sori ìtẹ ẹranko na; ilẹ-ọba rẹ̀ si ṣokunkun; nwọn si nge ahọn wọn jẹ nitori irora.