Ifi 16:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si gbọ́ ohùn nla kan lati inu tẹmpili wá, nwi fun awọn angẹli meje nì pe, Ẹ lọ, ẹ si tú ìgo ibinu Ọlọrun wọnni si ori ilẹ aiye.

2. Ekini si lọ, o si tú ìgo tirẹ̀ si ori ilẹ aiye; egbò kikẹ̀ ti o si dibajẹ si dá awọn enia ti o ni àmi ẹranko na, ati awọn ti nforibalẹ fun aworan rẹ̀.

3. Ekeji si tú ìgo tirẹ̀ sinu okun; o si dabi ẹ̀jẹ okú enia: gbogbo ọkàn alãye si kú ninu okun.

4. Ẹkẹta si tú ìgo tirẹ̀ sinu odò, ati si orisun awọn omi; nwọn si di ẹ̀jẹ.

5. Mo si gbọ́ angẹli ti omi nì wipe, Olododo ni Iwọ Ẹni-Mimọ́, ẹniti o mbẹ, ti o si ti wà, nitoriti iwọ ṣe idajọ bayi.

Ifi 16