Ifi 13:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́.

10. Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ́ awọn enia mimọ́ gbé wà.

11. Mo si ri ẹranko miran goke lati inu ilẹ wá; o si ni iwo meji bi ọdọ-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni.

12. O si nlò gbogbo agbara ẹranko ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san.

13. O si nṣe ohun iyanu nla, ani ti o fi nmu iná sọkalẹ lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia.

14. O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.

15. A si fi fun u lati fi ẹmí fun aworan ẹranko na ki o mã sọ̀rọ, ki o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na.

16. O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ̀ ati talakà, omnira ati ẹrú, ki a fi àmi kan fun wọn li ọwọ́ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn:

Ifi 13