30. Nigbati awọn arakunrin si mọ̀, nwọn mu u sọkalẹ lọ si Kesarea, nwọn si rán a lọ si Tarsu.
31. Nigbana ni ijọ wà li alafia yi gbogbo Judea ká ati ni Galili ati ni Samaria, nwọn nfẹsẹmulẹ; nwọn nrìn ni ìbẹru Oluwa, ati ni itunu Ẹmí Mimọ́, nwọn npọ̀ si i.
32. O si ṣe, bi Peteru ti nkọja nlà ẹkùn gbogbo lọ, o sọkalẹ tọ̀ awọn enia mimọ́ ti ngbe Lidda pẹlu.
33. Nibẹ̀ li o ri ọkunrin kan ti a npè ni Enea ti o ti dubulẹ lori akete li ọdún mẹjọ, o ni àrun ẹ̀gba.
34. Peteru si wi fun u pe, Enea, Jesu Kristi mu ọ larada: dide, ki o si tún akete rẹ ṣe. O si dide lojukanna.
35. Gbogbo awọn ti ngbe Lidda ati Saroni si ri i, nwọn si yipada si Oluwa.
36. Ọmọ-ẹhin kan si wà ni Joppa ti a npè ni Tabita, ni itumọ̀ rẹ̀ ti a npè ni Dorka: obinrin yi pọ̀ ni iṣẹ ore, ati itọrẹ-ãnu ti o ṣe.
37. O si ṣe ni ijọ wọnni, ti o ṣaisàn, o si kú: nigbati nwọn wẹ̀ ẹ tan, nwọn tẹ́ ẹ si yara kan loke.