Iṣe Apo 6:9-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Ṣugbọn awọn kan dide ninu awọn ti sinagogu, ti a npè ni ti awọn Libertine, ati ti ara Kirene, ati ti ara Aleksandria, ati ninu awọn ara Kilikia, ati ti Asia nwọn mba Stefanu jiyàn.

10. Nwọn kò si le kò ọgbọ́n ati ẹmí ti o fi nsọrọ loju.

11. Nigbana ni nwọn bẹ̀ abẹtẹlẹ awọn ọkunrin, ti nwọn nwipe, Awa gbọ́ ọkunrin yi nsọ ọrọ-odi si Mose ati si Ọlọrun.

12. Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ.

Iṣe Apo 6