Iṣe Apo 3:4-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa.

5. O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn.

6. Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin.

7. O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun.

8. O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun.

9. Gbogbo enia si ri i, o nrìn, o si nyìn Ọlọrun:

10. Nwọn si mọ̀ pe on li o ti joko nṣagbe li ẹnu-ọ̀nà Daradara ti tẹmpili: hà si ṣe wọn, ẹnu si yà wọn gidigidi si ohun ti o ṣe lara rẹ̀.

11. Bi arọ ti a mu larada si ti di Peteru on Johanu mu, gbogbo enia jumọ sure jọ tọ̀ wọn lọ ni iloro ti a npè ni ti Solomoni, ẹnu yà wọn gidigidi.

Iṣe Apo 3