Iṣe Apo 28:29-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Nigbati o si ti sọ ọ̀rọ wọnyi fun wọn tan, awọn Ju lọ, nwọn ba ara wọn jiyàn pipọ.

30. Paulu si gbe ile àgbawọ rẹ̀ lọdun meji tọ̀tọ, o si ngbà gbogbo awọn ti o wọle tọ̀ ọ wá,

31. O nwasu ijọba Ọlọrun, o si nfi igboiya gbogbo kọ́ni li ohun wọnni ti iṣe ti Jesu Kristi Oluwa, ẹnikan kò da a lẹkun.

Iṣe Apo 28