1. Bi a si ti pinnu rẹ̀ pe ki a wọ̀ ọkọ lọ si Itali, nwọn fi Paulu, ati awọn ondè miran kan pẹlu, le balogun ọrún kan lọwọ, ti a npè ni Juliu, ti ẹgbẹ ọmọ-ogun Augustu.
2. Nigbati a si wọ̀ ọkọ̀ Adramittiu kan, ti nfẹ lọ si awọn ilu ti o wà leti okun Asia, awa ṣikọ̀: Aristarku, ara Makedonia ti Tessalonika, wà pẹlu wa.
3. Ni ijọ keji awa de Sidoni. Juliu si ṣe inu rere si Paulu, o si bùn u láye ki o mã tọ̀ awọn ọrẹ́ rẹ̀ lọ lati ri itọju.
4. Nigbati awa si ṣikọ̀ nibẹ̀, awa lọ lẹba Kipru, nitoriti afẹfẹ ṣọwọ òdi.