Iṣe Apo 24:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ.

4. Ṣugbọn ki emi ki o má bà da ọ duro pẹ titi, mo bẹ̀ ọ ki o fi iyọnu rẹ gbọ́ ọ̀rọ diẹ li ẹnu wa.

5. Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene:

6. Ẹniti o gbidanwo lati bà tẹmpili jẹ: ti awa si mu, ti awa fẹ ba ṣe ẹjọ gẹgẹ bi ofin wa.

7. Ṣugbọn Lisia olori ogun de, o fi agbara nla gbà a li ọwọ wa:

8. O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀.

9. Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.

10. Nigbati bãlẹ ṣapẹrẹ si i pe ki o sọ̀rọ, Paulu si dahùn wipe, Bi mo ti mọ̀ pe lati ọdún melo yi wá, ni iwọ ti ṣe onidajọ orilẹ-ede yi, tayọtayọ ni ng o fi wi ti ẹnu mi.

Iṣe Apo 24