Iṣe Apo 23:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Paulu si tẹjumọ igbimọ, o ni, Ará, emi ti nfi gbogbo ẹri-ọkàn rere lò aiye mi niwaju Ọlọrun titi fi di oni yi.

2. Anania olori alufa si paṣẹ fun awọn ti o duro tì i pe, ki o gbún u li ẹnu.

3. Nigbana ni Paulu wi fun u pe, Ọlọrun yio lù ọ, iwọ ogiri ti a kùn li ẹfun: iwọ joko lati dajọ mi ni gẹgẹ bi ofin, iwọ si pè ki a lù mi li òdi si ofin?

4. Awọn ti o duro tì i si wipe, Olori alufa Ọlọrun ni iwọ ngàn?

5. Paulu si wipe, Ará, emi kò mọ̀ pe olori alufa ni: nitori a ti kọ ọ pe, Iwọ kò gbọdọ sọ̀rọ olori awọn enia rẹ ni buburu.

Iṣe Apo 23