Iṣe Apo 21:14-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nigbati a kò le pa a li ọkàn dà, awa dakẹ, wipe, Ifẹ ti Oluwa ni ki a ṣe.

15. Lẹhin ijọ wọnni, awa palẹmọ, a si gòke lọ si Jerusalemu.

16. Ninu awọn ọmọ-ẹhin lati Kesarea ba wa lọ, nwọn si mu Mnasoni ọmọ-ẹhin lailai kan pẹlu wọn, ará Kipru, lọdọ ẹniti awa ó gbé wọ̀.

17. Nigbati awa si de Jerusalemu, awọn arakunrin si fi ayọ̀ gbà wa.

18. Ni ijọ keji awa ba Paulu lọ sọdọ Jakọbu; gbogbo awọn alàgba si wà nibẹ̀.

19. Nigbati o si kí wọn tan, o ròhin ohun gbogbo lẹsẹsẹ ti Ọlọrun ṣe lãrin awọn Keferi nipa iṣẹ-iranṣẹ rẹ̀.

20. Nigbati nwọn si gbọ́, nwọn yin Ọlọrun logo, nwọn si wi fun u pe, Arakunrin, iwọ ri iye ẹgbẹgbẹrun ninu awọn Ju ti o gbagbọ, gbogbo nwọn li o si ni itara fun ofin.

21. Nwọn si ti ròhin rẹ fun wọn pe, Iwọ nkọ́ gbogbo awọn Ju ti o wà lãrin awọn Keferi pe, ki nwọn ki o kọ̀ Mose silẹ, o si nwi fun wọn pe ki nwọn ki o máṣe kọ awọn ọmọ wọn ni ilà mọ́, ati ki nwọn ki o máṣe rìn gẹgẹ bi àṣa wọn.

22. Njẹ ewo ni ṣiṣe? ijọ kò le ṣaima pejọ pọ̀: dajudaju nwọn ó gbọ́ pe, iwọ de.

Iṣe Apo 21