Iṣe Apo 13:36-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ.

37. Ṣugbọn ẹniti Ọlọrun ji dide kò ri idibajẹ.

38. Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin:

39. Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose.

40. Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe;

41. Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin.

42. Bi nwọn si ti njade, nwọn bẹ̀bẹ pe ki a sọ̀rọ wọnyi fun wọn li ọjọ isimi ti mbọ̀.

Iṣe Apo 13