Iṣe Apo 10:24-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nijọ keji nwọn si wọ̀ Kesarea. Korneliu si ti nreti wọn, o si ti pè awọn ibatan ati awọn ọrẹ́ rẹ̀ timọtimọ jọ.

25. O si ṣe bi Peteru ti nwọle, Korneliu pade rẹ̀, o wolẹ li ẹsẹ rẹ̀, o si foribalẹ fun u.

26. Ṣugbọn Peteru gbé e dide, o ni, Dide; enia li emi tikarami pẹlu.

Iṣe Apo 10