5. Nitori nitotọ ni Johanu fi omi baptisi; ṣugbọn a o fi Ẹmí Mimọ́ baptisi nyin, kì iṣe ọjọ pupọ lati oni lọ.
6. Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi?
7. O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀.
8. Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye.
9. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn.
10. Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn;
11. Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.
12. Nigbana ni nwọn pada ti ori òke ti a npè ni Olifi lọ si Jerusalemu, ti o sunmọ Jerusalemu ni ìwọn ìrin ọjọ isimi kan.