22. Máṣe fi ikanju gbe ọwọ́ le ẹnikẹni, bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ alabapin ninu ẹ̀ṣẹ̀ awọn ẹlomiran: pa ara rẹ mọ́ ni ìwa funfun.
23. Máṣe mã mu omi nikan, ṣugbọn mã lo waini diẹ nitori inu rẹ, ati nitori ailera rẹ igbakugba.
24. Ẹ̀ṣẹ awọn ẹlomiran a mã han gbangba, a mã lọ ṣãju si idajọ; ti awọn ẹlomiran pẹlu a si mã tẹle wọn.
25. Bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni iṣẹ rere wà ti nwọn hàn gbangba; awọn iru miran kò si le farasin.