1. MÁṢE ba alàgba wi, ṣugbọn ki o mã gba a niyanju bi baba; awọn ọdọmọkunrin bi arakunrin;
2. Awọn àgba obinrin bi iya; awọn ọdọmọbirin bi arabinrin ninu ìwa mimọ́.
3. Bọ̀wọ fun awọn opó ti iṣe opó nitõtọ.
4. Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun.
5. Njẹ ẹniti iṣe opó nitõtọ, ti o ṣe on nikan, a mã gbẹkẹle Ọlọrun, a si mã duro ninu ẹ̀bẹ ati ninu adura lọsán ati loru.
6. Ṣugbọn ẹniti o ba fi ara rẹ̀ fun aiye jijẹ, o kú nigbati o wà lãye.
7. Nkan wọnyi ni ki iwọ ki o si mã palaṣẹ, ki nwọn ki o le wà lailẹgan.
8. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò bá pèse fun awọn tirẹ, papa fun awọn ará ile rẹ̀, o ti sẹ́ igbagbọ́, o buru ju alaigbagbọ́ lọ.
9. Máṣe kọ orukọ ẹniti o ba din ni ọgọta ọdún silẹ bi opó, ti o ti jẹ obinrin ọkọ kan,
10. Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo.