1. ṢUGBỌN niti akokò ati ìgba wọnni, ará, ẹnyin kò tun fẹ ki a kọ ohunkohun si nyin,
2. Nitoripe ẹnyin tikaranyin mọ̀ dajudaju pe, ọjọ Oluwa mbọ̀wá gẹgẹ bi olè li oru.
3. Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà.
4. Ṣugbọn ẹnyin, ará, kò si ninu òkunkun, ti ọjọ na yio fi de bá nyin bi olè.
5. Nitori gbogbo nyin ni ọmọ imọlẹ, ati ọmọ ọsán: awa kì iṣe ti oru, tabi ti òkunkun.
6. Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti nṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a mã ṣọna ki a si mã wa ni airekọja.
7. Nitori awọn ti nsùn, ama sùn li oru; ati awọn ti nmutipara, ama mutipara li oru.
8. Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsán, mã wà li airekọja, ki a mã gbé igbaiya igbagbọ́ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori.
9. Nitori Ọlọrun yàn wa ki iṣe si ibinu, ṣugbọn si ati ni igbala nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa,