2. Nitori ẹnyin mọ̀ irú aṣẹ ti a ti pa fun nyin lati ọdọ Jesu Oluwa.
3. Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, ani wiwà ni mimọ́ nyin, pe ki ẹnyin ki o takéte si àgbere:
4. Ki olukuluku nyin le mọ̀ bi on iba ti mã ko ohun èlo rẹ̀ ni ijanu ni ìwa-mimọ́ ati ni ọlá;
5. Kì iṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti kò mọ̀ Ọlọrun:
6. Ki ẹnikẹni máṣe rekọja, ki o má si ṣe ṣẹ arakunrin rẹ̀ ninu nkan na: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun nyin tẹlẹ, ti a si jẹri pẹlu.
7. Nitori Ọlọrun kò pè wa fun ìwa ẽri, ṣugbọn ni ìwamimọ́.
8. Nitorina ẹnikẹni ti o bá kọ̀, ko kọ̀ enia, bikoṣe Ọlọrun, ẹniti o fun nyin ni Ẹmí Mimọ́ rẹ̀ pẹlu.