1. NJẸ ọkunrin kan ara Benjamini si wà, a ma pe orukọ rẹ̀ ni Kiṣi, ọmọ Abeli, ọmọ Sesori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afia, ara Benjamini ọkunrin alagbara.
2. On si ni ọmọkunrin kan, ẹniti a npè ni Saulu, ọdọmọkunrin ti o yàn ti o si ṣe arẹwa, kò si si ẹniti o dara ju u lọ ninu gbogbo awọn ọmọ Israeli: lati ejika rẹ̀ lọ si oke, o ga jù gbogbo awọn enia na lọ.
3. Kẹtẹkẹtẹ Kiṣi baba Saulu si nù. Kiṣi si wi fun Saulu ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ mu ọkan ninu awọn iranṣẹkunrin pẹlu rẹ ki o si dide lọ wá kẹtẹkẹtẹ wọnni.
4. On kọja niha oke Efraimu, o si kọja niha ilẹ Saliṣa, ṣugbọn nwọn kò ri wọn: nwọn si kọja ni ilẹ Salimu, nwọn kò si si nibẹ; o si kọja ni ilẹ Benjamini, nwọn kò si ri wọn.
5. Nigbati nwọn de ilẹ Sufu, Saulu wi fun iranṣẹ-kọnrin rẹ̀ ẹniti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a yipada; ki baba mi ki o má ba fi ãjò awọn kẹtẹkẹtẹ silẹ, ki o si ma kọ ominu nitori wa.
6. O si wi fun u pe, Kiye si i, ẹni Ọlọrun kan wà ni ilu yi, o si ṣe ọkunrin ọlọla; gbogbo eyi ti o ba wi, a si ṣẹ: wá, ki a lọ si ibẹ̀; bọya yio fi ọ̀na ti a o gbà hàn wa.
7. Saulu si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Bi awa ba lọ, kili awa o mu lọ fun ọkunrin na? nitoripe akara tan ni apò wa, ko si si ọrẹ ti a o mu tọ̀ ẹni Ọlọrun na: kili awa ni?
8. Iranṣẹ na si da Saulu lohùn wipe, Mo ni idamẹrin ṣekeli fadaka lọwọ́, eyi li emi o fun ẹni Ọlọrun na, ki o le fi ọ̀na wa hàn wa.
9. (Ni Israeli latijọ, nigbati ọkunrin kan ba lọ bere lọdọ Ọlọrun, bayi ni ima wi, Wá, ẹ jẹ ki a lọ sọdọ arina na, nitori ẹni ti a npe ni woli nisisiyi, on ni a npe ni arina nigba atijọ ri)