12. Nwọn si bùn u li akara eso ọpọtọ ati ṣiri ajara gbigbẹ meji: nigbati o si jẹ ẹ tan, ẹmi rẹ̀ si sọji: nitoripe ko jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò si mu omi ni ijọ mẹta li ọsan, ati li oru.
13. Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan.
14. Awa si gbe ogun lọ siha gusu ti ara Keriti, ati si apa ti iṣe ti Juda, ati si iha gusu ti Kelebu; awa si kun Siklagi.
15. Dafidi si bi i lere pe, Iwọ le mu mi sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun yi lọ bi? On si wipe, Fi Ọlọrun bura fun mi, pe, iwọ kì yio pa mi, bẹ̃ni iwọ kì yio si fi mi le oluwa mi lọwọ; emi o si mu ọ sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun na lọ.
16. O si mu u sọkalẹ, si wõ, nwọn si tànka ilẹ, nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn si njo, nitori ikogun pupọ ti nwọn ko lati ilẹ awọn Filistini wá, ati lati ilẹ Juda.