4. Dafidi si tun bere lọdọ Oluwa. Oluwa si da a lohùn, o si wipe, Dide, ki o sọkalẹ lọ si Keila, nitoripe emi o fi awọn ara Filistia na le ọ lọwọ.
5. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ si Keila, nwọn si ba awọn ara Filistia jà, nwọn si ko ohun ọsìn wọn, nwọn si fi iparun nla pa wọn. Dafidi si gbà awọn ara Keila silẹ.
6. O si ṣe, nigbati Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sa tọ Dafidi lọ ni Keila, o sọkalẹ ton ti efodu kan lọwọ rẹ̀,
7. A si sọ fun Saulu pe, Dafidi wa si Keila. Saulu si wipe, Ọlọrun ti fi i le mi lọwọ; nitoripe a ti dí i mọ tan, nitori o wọ inu ilu ti o ni ilẹkun ati ikere.
8. Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀.