1. Sam 22:22-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Dafidi si wi fun Abiatari pe, emi ti mọ̀ ni ijọ na, nigbati Doegi ara Edomu nì ti wà nibẹ̀ pe, nitotọ yio sọ fun Saulu: nitori mi li a ṣe pa gbogbo idile baba rẹ.

23. Iwọ joko nihin lọdọ mi, máṣe bẹ̀ru, nitoripe ẹniti nwá ẹmi mi, o nwá ẹmi rẹ: ṣugbọn lọdọ mi ni iwọ o wà li ailewu.

1. Sam 22