1. Sam 22:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI si kuro nibẹ, o si sa si iho Adullamu; nigbati awọn arakunrin rẹ̀ ati idile baba rẹ̀ si gbọ́ ọ, nwọn si sọkalẹ tọ̀ ọ nibẹ.

2. Olukuluku ẹniti o ti wà ninu ipọnju, ati olukuluku ẹniti o ti jẹ gbesè, ati olukuluku ẹniti o wà ninu ibanujẹ, si ko ara wọn jọ sọdọ rẹ̀, on si jẹ olori wọn: awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ si to iwọn irinwo ọmọkunrin.

3. Dafidi si ti ibẹ̀ na lọ si Mispe ti Moabu: on si wi fun ọba Moabu pe, Jẹ ki baba ati iya mi, emi bẹ̀ ọ, wá ba ọ gbe, titi emi o fi mọ̀ ohun ti Ọlọrun yio ṣe fun mi.

4. O si mu wọn wá siwaju ọba Moabu; nwọn si ba a gbe ni gbogbo ọjọ ti Dafidi fi wà ninu ihò na.

5. Gadi woli si wi fun Dafidi pe, Máṣe gbe inu ihò na; yẹra, ki o si lọ si ilẹ Juda. Nigbana ni Dafidi si yẹra, o si lọ sinu igbo Hareti.

6. Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i;

7. Nigbana ni Saulu wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o duro tì i, pe, Njẹ, ẹ gbọ́, ẹnyin ara Benjamini, ọmọ Jesse yio ha fun olukuluku nyin ni oko ati ọgba ajara bi, ki o si sọ gbogbo nyin di olori ẹgbẹgbẹrun ati olori ọrọrun bi?

1. Sam 22