7. Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀.
8. Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba.
9. Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ.
10. O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu.
11. Saulu si sọ ẹṣín ti o wà lọwọ rẹ̀ na; o si wipe, Emi o pa Dafidi li apa mọ́ ogiri. Dafidi si yẹra kuro niwaju rẹ lẹ̃meji.
12. Saulu si bẹ̀ru Dafidi, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa kọ̀ Saulu.
13. Nitorina Saulu si mu u kuro lọdọ rẹ̀, o si fi i jẹ olori ogun ẹgbẹrun kan, o si nlọ, o si mbọ̀ niwaju awọn enia na.
14. Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
15. Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀.
16. Gbogbo Israeli ati Juda si fẹ Dafidi, nitoripe a ma lọ a si ma bọ̀ niwaju wọn.
17. Saulu si wi fun Dafidi pe, Wo Merabu ọmọbinrin mi, eyi agbà, on li emi o fi fun ọ li aya: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alagbara fun mi, ki o si ma ja ija Oluwa. Nitoriti Saulu ti wi bayi pe, Màṣe jẹ ki ọwọ́ mi ki o wà li ara rẹ̀; ṣugbọn jẹ ki ọwọ́ awọn Filistini ki o wà li ara rẹ̀.
18. Dafidi si wi fun Saulu pe, Tali emi, ati ki li ẹmi mi, tabi idile baba mi ni Israeli, ti emi o fi wa di ana ọba.
19. O si ṣe, li akoko ti a ba fi Merabu ọmọbinrin Saulu fun Dafidi, li a si fi i fun Adrieli ara Meholati li aya.