1. Sam 16:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.

8. Jesse si pe Abinadabu, o si mu ki o kọja niwaju Samueli. On si wipe, Oluwa kò si yan eleyi.

9. Jesse si mu ki Ṣamma ki o kọja. On si wipe, Oluwa kò si yàn eyi.

10. Jesse si tun mu ki awọn ọmọ rẹ̀ mejeje kọja niwaju Samueli. Samueli si wi fun Jesse pe, Oluwa kò yan awọn wọnyi.

11. Samueli si bi Jesse lere pe, gbogbo awọn ọmọ rẹ li o wà nihin bi? On si dahun wipe, abikẹhin wọn li o kù, sa wõ, o nṣọ agutan. Samueli si wi fun Jesse pe, Ranṣẹ ki o si mu u wá: nitoripe awa kì yio joko titi on o fi dé ihinyi.

12. O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi.

13. Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.

14. Ṣugbọn Ẹmi Oluwa fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa si nyọ ọ li ẹnu.

15. Awọn iranṣẹ Saulu si wi fun u pe, Jọwọ, sa wõ ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun nyọ ọ li ẹnu.

16. Njẹ ki oluwa wa fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà niwaju rẹ̀ lati wá ọkunrin kan ti o mọ̀ ifi duru kọrin: yio si ṣe nigbati ẹmi buburu na lati ọdọ̀ Ọlọrun wá ba de si ọ, yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara dùru, iwọ o si sàn.

17. Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ ba mi wá ọkunrin kan, ti o mọ̀ iṣẹ́ orin daju, ki ẹ si mu u tọ̀ mi wá.

18. Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.

1. Sam 16