12. O si ranṣẹ, o si mu u wá. On si jẹ ẹnipupa, ti o lẹwà loju, o si dara lati ma wò. Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si fi ororo sà a li àmi: nitoripe on na li eyi.
13. Nigbana ni Samueli mu iwo ororo, o si fi yà a si ọ̀tọ larin awọn arakunrin rẹ̀; Ẹmi Oluwa si bà le Dafidi lati ọjọ na lọ, Samueli si dide, o si lọ si Rama.
14. Ṣugbọn Ẹmi Oluwa fi Saulu silẹ, ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa si nyọ ọ li ẹnu.
15. Awọn iranṣẹ Saulu si wi fun u pe, Jọwọ, sa wõ ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun nyọ ọ li ẹnu.
16. Njẹ ki oluwa wa fi aṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ti o wà niwaju rẹ̀ lati wá ọkunrin kan ti o mọ̀ ifi duru kọrin: yio si ṣe nigbati ẹmi buburu na lati ọdọ̀ Ọlọrun wá ba de si ọ, yio si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara dùru, iwọ o si sàn.
17. Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Njẹ ẹ ba mi wá ọkunrin kan, ti o mọ̀ iṣẹ́ orin daju, ki ẹ si mu u tọ̀ mi wá.
18. Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.
19. Saulu si ran iranṣẹ si Jesse wipe, ran Dafidi ọmọ rẹ si mi, ẹniti o nṣọ agutan.
20. Jesse si mu kẹtẹkẹtẹ, o si di ẹrù akara le e, ati igò ọti-waini, ati ọmọ ewurẹ; o si ran wọn nipa ọwọ Dafidi ọmọ rẹ̀ si Saulu.
21. Dafidi si tọ Saulu lọ, o si duro niwaju rẹ̀: on si fẹ ẹ gidigidi; Dafidi si wa di ẹniti nrù ihamọra rẹ̀.
22. Saulu si ranṣẹ si Jesse pe, Jẹ ki Dafidi, emi bẹ ọ, duro niwaju mi; nitori ti o wù mi.
23. O si ṣe, nigbati ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá ba de si Saulu, Dafidi a si fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru: a si san fun Saulu, ara rẹ̀ a si da; ẹmi buburu na, a si fi i silẹ.