1. Sam 16:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si wi fun Samueli pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kãnu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ̀ ọ lati ma jọba lori Israeli? Fi ororo kún iwo rẹ, ki o si lọ, emi o rán ọ tọ̀ Jesse ara Betlehemu: nitoriti emi ti ri ọba kan fun ara mi ninu awọn ọmọ rẹ̀.

2. Samueli si wi pe, Emi o ti ṣe lọ? bi Saulu ba gbọ́ yio si pa mi. Oluwa si wi fun u pe, mu ọdọ-malu kan li ọwọ́ rẹ, ki o si wipe, Emi wá rubọ si Oluwa.

3. Ki o si pe Jesse si ibi ẹbọ na, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe hàn ọ: iwọ o si ta ororo si ori ẹniti emi o da orukọ fun ọ.

4. Samueli si ṣe eyi ti Oluwa wi fun u, o sì wá si Betlehemu. Awọn agbà ilu na si bẹ̀ru nitori wiwá rẹ̀, nwọn si wipe, Alafia ki iwọ ba wá si bi?

5. On si dahùn wipe, Alafia ni: emi wá rubọ si Oluwa; ẹ ṣe ara nyin ni mimọ́, ki ẹ si wá pẹlu mi si ibi ẹbọ na. On si yà Jesse sí mimọ́, ati awọn ọmọ rẹ̀, o si pe wọn si ẹbọ na.

6. O si ṣe nigbati nwọn de, o ri Eliabu, o si wipe, nitotọ ẹni-àmi-ororo Oluwa mbẹ niwaju rẹ̀.

7. Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.

8. Jesse si pe Abinadabu, o si mu ki o kọja niwaju Samueli. On si wipe, Oluwa kò si yan eleyi.

9. Jesse si mu ki Ṣamma ki o kọja. On si wipe, Oluwa kò si yàn eyi.

10. Jesse si tun mu ki awọn ọmọ rẹ̀ mejeje kọja niwaju Samueli. Samueli si wi fun Jesse pe, Oluwa kò yan awọn wọnyi.

1. Sam 16