1. Sam 13:10-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i.

11. Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi.

12. Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na.

13. Samueli si wi fun Saulu pe, iwọ kò hu iwà ọlọgbọ́n: iwọ ko pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ, ti on ti pa li aṣẹ fun ọ: nitori nisisiyi li Oluwa iba fi idi ijọba rẹ kalẹ̀ lori Israeli lailai.

14. Ṣugbọn nisisiyi ijọba rẹ kì yio duro pẹ: Oluwa ti wá fun ara rẹ̀ ọkunrin ti o wù u li ọkàn rẹ̀, Oluwa paṣẹ fun u ki o ṣe olori fun awọn enia rẹ̀, nitoripe iwọ kò pa aṣẹ ti Oluwa fi fun ọ mọ.

15. Samueli si dide, o si lọ lati Gilgali si Gibea ti Benjamini. Saulu si ka awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, o jẹ iwọ̀n ẹgbẹta ọkunrin.

16. Saulu, ati Jonatani ọmọ rẹ̀, ati awọn enia na ti o wà lọdọ wọn si joko ni Gibea ti Benjamini, ṣugbọn awọn Filistini do ni Mikmaṣi.

17. Ẹgbẹ awọn onisùmọ̀mi mẹta jade ni ibudo awọn Filistini: ẹgbẹ kan gbà ọ̀na ti Ofra, si ilẹ Ṣuali.

18. Ẹgbẹ kan si gba ọ̀na Bet-horoni: ati ẹgbẹ kan si gbà ọ̀na agbegbe nì ti o kọju si afonifoji Seboimu ti o wà ni iha iju.

19. Kò si alagbẹdẹ ninu gbogbo ilẹ Israeli: nitori ti awọn Filistini wipe, Ki awọn Heberu ki o má ba rọ idà tabi ọ̀kọ.

20. Ṣugbọn gbogbo Israeli a ma tọ̀ awọn Filistini lọ, olukuluku lati pọ́n doje rẹ̀, ati ọ̀kọ rẹ̀, ati ãke rẹ̀, ati ọ̀ṣọ rẹ̀.

21. Ṣugbọn nwọn ni ayùn fun ọ̀ṣọ, ati fun ọ̀kọ, ati fun òya-irin ti ilẹ, ati fun ãke, ati lati pọn irin ọpa oluṣọ malu.

22. Bẹ̃li o si ṣe li ọjọ ijà, ti a kò ri idà, tabi ọ̀kọ lọwọ ẹnikẹni ninu awọn enia ti o wà lọdọ Saulu ati Jonatani; lọdọ Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ li a ri.

23. Awọn ọmọ-ogun Filistini jade lọ si ikọja Mikmaṣi.

1. Sam 13