1. Sam 12:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nigbati ẹnyin si ri pe Nahaṣi ọba awọn ọmọ Ammoni tọ̀ nyin wá, ẹnyin wi fun mi pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ọba yio jẹ lori wa: nigbati Oluwa Ọlọrun nyin jẹ ọba nyin.

13. Njẹ nisisiyi wo ọba na ti ẹnyin yàn, ati ti ẹnyin fẹ, kiye si i, Oluwa fi ọba jẹ fun nyin.

14. Bi ẹnyin ba bẹ̀ru Oluwa, ti ẹnyin si sin i, ti ẹnyin si gbọ́ ohùn rẹ̀, ti ẹnyin ko si tapa si ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ati ọba nyin ti o jẹ lori nyin yio ma wà lẹhin Oluwa Ọlọrun nyin.

15. Ṣugbọn bi ẹnyin ko ba gbà ohun Oluwa gbọ́, ti ẹ ba si tàpá si ọ̀rọ Oluwa, ọwọ́ Oluwa yio wà lara nyin si ibi, bi o ti wà lara baba nyin.

16. Nitorina nisisiyi ẹ duro ki ẹ si wo nkan nla yi, ti Oluwa yio ṣe li oju nyin.

17. Oni ki ọjọ ikore ọka bi? emi o kepe Oluwa, yio si ran ãra ati ojò; ẹnyin o si mọ̀, ẹnyin o si ri pe iwabuburu nyin pọ̀, ti ẹnyin ṣe li oju Oluwa ni bibere ọba fun ara nyin.

18. Samueli si kepe Oluwa, Oluwa si ran ãra ati ojò ni ọjọ na: gbogbo enia si bẹru Oluwa pupọ ati Samueli.

1. Sam 12