9. O si ri bẹ̃ pe, nigbati o yi ẹhin rẹ̀ pada lati lọ kuro lọdọ Samueli, Ọlọrun si fun u li ọkàn miran: gbogbo àmi wọnni si ṣẹ li ọjọ na.
10. Nigbati nwọn si de ibẹ si oke na, si kiye si i, ẹgbẹ awọn woli pade rẹ̀, Ẹmi Ọlọrun si bà le e, on si sọtẹle larin wọn.
11. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ ri pe o nsọtẹlẹ larin awọn woli, awọn enia si nwi fun ara wọn pe, Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?
12. Ẹnikan lati ibẹ na wá si dahùn, o si wipe, ṣugbọn tani baba wọn? Bẹ̃li o si wà li owe, Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?
13. Nigbati o sọtẹlẹ tan, o si lọ si ibi giga nì.
14. Arakunrin Saulu kan si wi fun u ati fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Nibo li ẹnyin ti lọ? On si wipe, lati wá awọn kẹtẹkẹtẹ ni: nigbati awa ri pe nwọn kò si nibi kan, awa si tọ Samueli lọ.
15. Arakunrin Saulu na si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ̀ ọ, ohun ti Samueli wi fun ọ.
16. Saulu si wi fun arakunrin rẹ̀ pe, On ti sọ fun wa dajudaju pe, nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ nã. Ṣugbọn ọ̀ran ijọba ti Samueli sọ, on kò sọ fun u.
17. Samueli si pe gbogbo enia jọ siwaju Oluwa ni Mispe.
18. O si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi mu Israeli goke ti Egipti wá, mo si gbà nyin kuro lọwọ́ awọn ara Egipti, ati kuro lọwọ́ gbogbo ijọba wọnni ti o pọn nyin loju.
19. Ẹnyin si kọ̀ Ọlọrun nyin loni, ẹniti on tikara rẹ́ ti gbà nyin kuro lọwọ́ gbogbo awọn ọta nyin, ati gbogbo wahala nyin; ẹnyin si ti wi fun u pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn awa nfẹ ki o fi ẹnikan jọba lori wa. Nisisiyi ẹ duro niwaju Oluwa nipa ẹyà nyin, ati nipa ẹgbẹgbẹrun nyin.