2. Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.
3. Bẹ̃ni ki iṣe bi ẹniti nlo agbara lori ijọ, ṣugbọn ki ẹ ṣe ara nyin li apẹrẹ fun agbo.
4. Nigbati olori Oluṣọ-agutan ba si fi ara hàn, ẹnyin ó gbà ade ogo ti kì iṣá.
5. Bẹ̃ pẹlu, ẹnyin ipẹ̃rẹ, ẹ tẹriba fun awọn àgba. Ani, gbogbo nyin, ẹ mã tẹriba fun ara nyin, ki ẹ si fi irẹlẹ wọ̀ ara nyin li aṣọ: nitori Ọlọrun kọ oju ija si awọn agberaga, ṣugbọn O nfi ore-ọfẹ fun awọn onirẹlẹ.