1. Pet 5:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Tirẹ̀ li ogo ati agbara titi lailai. Amin.

12. Nipa Silfanu, arakunrin wa olõtọ gẹgẹbi mo ti ka a si, ni mo kọwe kukuru si nyin, ti mo ngbà nyin niyanju, ti mo si njẹri pe, eyi ni otitọ ore-ọfẹ Ọlọrun: ẹ duro ṣinṣin ninu rẹ̀.

13. Ijọ ti mbẹ ni Babiloni, ti a yàn pẹlu nyin, kí nyin; bẹ̃ si ni Marku ọmọ mi pẹlu.

14. Ẹ fi ifẹnukonu ifẹ kí ara nyin. Amin.

1. Pet 5