2. Dafidi si wi fun Joabu ati awọn olori enia pe, Lọ ikaye Israeli lati Beerṣeba titi de Dani; ki o si mu iye wọn fun mi wá, ki emi ki o le mọ̀ iye wọn.
3. Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi.
4. Ṣugbọn ọ̀rọ ọba bori ti Joabu, nitorina Joabu jade lọ, o si la gbogbo Israeli ja, o si de Jerusalemu.
5. Joabu si fi apapọ iye awọn enia na fun Dafidi. Gbogbo Israeli jasi ẹgbẹrun ẹgbẹrun ati ọke marun enia ti nkọ idà: Juda si jasi ọkẹ mẹtalelogun le ẹgbãrun ọkunrin ti nkọ idà.
6. Ṣugbọn Lefi ati Benjamini ni kò kà pẹlu wọn: nitori ọ̀rọ ọba jẹ irira fun Joabu.
7. Nkan yi si buru loju Ọlọrun; o si kọlù Israeli.
8. Dafidi si wi fun Ọlọrun pe, Emi ti ṣẹ̀ gidigidi ni ṣiṣe nkan yi: ṣugbọn nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, mu ẹ̀ṣẹ iranṣẹ rẹ kuro; nitoriti mo hùwa wère gidigidi.
9. Oluwa si wi fun Gadi, ariran Dafidi pe,