Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi.