1. Kro 21:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SATANI si duro tì Israeli, o si tì Dafidi lati ka iye Israeli.

2. Dafidi si wi fun Joabu ati awọn olori enia pe, Lọ ikaye Israeli lati Beerṣeba titi de Dani; ki o si mu iye wọn fun mi wá, ki emi ki o le mọ̀ iye wọn.

3. Joabu si wipe, Ki Oluwa ki o mu awọn enia rẹ pọ̀ si i ni igba ọgọrun jù bi wọn ti wà: ọba, oluwa mi, gbogbo wọn kì iha ṣe iranṣẹ oluwa mi? ẽṣe ti oluwa mi fi mbère nkan yi? ẽṣe ti on o fi mu Israeli jẹbi.

1. Kro 21