1. Kro 2:6-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn jẹ marun.

7. Ati awọn ọmọ Karmi; Akari, oniyọnu Israeli, ẹniti o dẹṣẹ niti ohun iyasọtọ̀.

8. Awọn ọmọ Etani; Asariah.

9. Awọn ọmọ Hesroni pẹlu ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai.

10. Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, ijoye awọn ọmọ Juda;

11. Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi.

12. Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse,

13. Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu àtẹle, ati Ṣimma ẹkẹta.

14. Netanneeli ẹkẹrin, Raddai ẹkarun,

15. Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje:

16. Awọn arabinrin wọn ni Seruiah ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruiah; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaeli, mẹta.

17. Abigaili si bi Amasa: baba Amasa si ni Jeteri ara Iṣmeeli.

18. Kalebu ọmọ Hesroni si bi ọmọ lati ọdọ Asuba aya rẹ̀, ati lati ọdọ Jeriotu: awọn ọmọ rẹ̀ ni wọnyi; Jeṣeri, ati Ṣohabu, ati Ardoni.

1. Kro 2