1. Kro 2:48-55 Yorùbá Bibeli (YCE)

48. Maaka obinrin Kalebu bi Ṣeberi, ati Tirhana.

49. On si bi Ṣaafa baba Madmana, Ṣefa baba Makbena, ati baba Gibea: ọmọbinrin Kalebu si ni Aksa.

50. Wọnyi li awọn ọmọ Kalebu ọmọ Huri, akọbi Efrata; Ṣobali baba Kirjat-jearimu,

51. Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi.

52. Ati Ṣobali baba Kirjat-jearimu ni ọmọ; Haroe, ati idaji awọn ara Manaheti.

53. Ati awọn idile Kirjat-jearimu; awọn ara Itri, ati awọn ara Puti, ati awọn ara Ṣummati, ati awọn ara Misrai; lọdọ wọn li awọn ara Sareati, ati awọn ara Ẹstauli ti wá.

54. Awọn ọmọ Salma; Betlehemu, ati awọn ara Netofati, Ataroti, ile Joabu, ati idaji awọn ara Manahati, awọn ara Sori.

55. Ati idile awọn akọwe ti ngbe Jabesi; awọn ara Tira, awọn ara Ṣimeati, ati awọn ara Sukati. Wọnyi li awọn ara Keni ti o ti ọdọ Hemati wá, baba ile Rekabu.

1. Kro 2