25. Ati awọn ọmọ Jerahmeeli, akọbi Hesroni, ni Rama akọbi, ati Buna, ati Oreni, ati Osemu, ati Ahijah.
26. Jerahmeeli si ni obinrin miran pẹlu, orukọ ẹniti ijẹ Atara; on ni iṣe iya Onamu.
27. Awọn ọmọ Ramu akọbi Jerahmeeli ni, Maasi, ati Jamini, ati Ekeri.
28. Awọn ọmọ Onamu si ni, Ṣammai, ati Jada. Awọn ọmọ Ṣammai ni; Nadabu ati Abiṣuri.
29. Orukọ aya Abiṣuri si njẹ Abihaili, on si bi Abani, ati Molidi fun u.
30. Ati awọn ọmọ Nadabu; Seledi, ati Appaimu: ṣugbọn Seledi kú laini ọmọ.
31. Ati awọn ọmọ Appaimu; Iṣi. Ati awọn ọmọ Iṣi; Ṣeṣani. Ati awọn ọmọ Ṣeṣani. Ahlai.